Who cast that first fateful tomato that started the La Tomatina revolution? The reality is no one knows. Maybe it was an anti-Franco rebellion, or a carnival that got out of hand. According to the most popular version of the story, during the 1945 festival of Los Gigantes (a giant paper mâché puppet parade), locals were looking to stage a brawl to get some attention. They happened upon a vegetable cart nearby and started hurling ripe tomatoes. Innocent onlookers got involved until the scene escalated into a massive melee of flying fruit. The instigators had to repay the tomato vendors, but that didn't stop the recurrence of more tomato fights—and the birth of a new tradition.
Fearful of an unruly escalation, authorities enacted, relaxed, and then reinstated a series of bans in the 1950s. In 1951, locals who defied the law were imprisoned until public outcry called for their release. The most famous effrontery to the tomato bans happened in 1957 when proponents held a mock tomato funeral complete with a coffin and procession. After 1957, the local government decided to roll with the punches, set a few rules in place, and embraced the wacky tradition.
Though the tomatoes take center stage, a week of festivities lead up to the final showdown. It's a celebration of Buñol's patron saints, the Virgin Mary and St. Louis Bertrand, with street parades, music, and fireworks in joyous Spanish fashion. To build up your strength for the impending brawl, an epic paella is served on the eve of the battle, showcasing an iconic Valencian dish of rice, seafood, saffron, and olive oil.
Today, this unfettered festival has some measure of order. Organizers have gone so far as to cultivate a special variety of unpalatable tomatoes just for the annual event. Festivities kick off around 10 a.m. when participants race to grab a ham fixed atop a greasy pole. Onlookers hose the scramblers with water while singing and dancing in the streets. When the church bell strikes noon, trucks packed with tomatoes roll into town, while chants of "To-ma-te, to-ma-te!" reach a crescendo.
Then, with the firing of a water cannon, the main event begins. That's the green light for crushing and launching tomatoes in all-out attacks against fellow participants. Long distance tomato lobbers, point-blank assassins, and medium range hook shots. Whatever your technique, by the time it's over, you will look (and feel) quite different. Nearly an hour later, tomato-soaked bombers are left to play in a sea of squishy street salsa with little left resembling a tomato to be found. A second cannon shot signals the end of the battle. | Tani o jù tomato málegbàgbé àkọ́kọ́ yẹn tó bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn La Tomatina náà. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ẹni tí o mọ̀. Bóyá ìṣọ̀tẹ̀ ìlòdìsí-Franko kan ni, tabi ayẹyẹ-ojú-pópó kan tí ó bọ́wọ́ sórí ni. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà-ìtàn náà kan tó wọ́pọ̀ julọ, ní àkókò àjọ̀dún Los Gigantes ti ọdun 1945 (tí ó máa n wáyé nípa ríru òmìrán ọmọ-lá-n-gidi kan tí a fi ẹrọ̀fọ̀ bébà ṣe káàkiri), tí àwọn ọmọ onílẹ̀ kan n wọ́nà lati ṣe jàgìdíjàgan kan kí aráyé lè ba à tẹ́tí sí ẹ̀hónú wọn. N ṣe ni wọn ṣèèṣì ṣe alábàápàdé ọmọlanke ẹlẹ́fọ̀ọ́ kan nítòsi, tí wọn sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní sọ tomato pípọ́n lu ara wọn. Awọn tí n wòran jẹ́jẹ́ pẹ̀lú nkò mọ̀ igbà tí wọn darapọ̀ mọ́ wọn títí tí gbogbo rẹ̀ fi di iṣu-ata-yán-an-yan-an nla tí èṣo tí n fò fìrì kiri nínú afẹ́fẹ́. Àwọn adárúgúdù sílẹ̀ ọjọ́ náà ní lati sanwo fún àwọn onítomati ọ̀hùn, sùgbọ́n èyí kò kúkú dẹ́kun pé kí ìjà onítòmátì ma tún ṣe aláì-wáyé mọ́ – èyí ni bí ìṣẹ̀dálẹ̀ tuntun kan tún ṣe dáyé. Pẹ́lù ìbẹ̀rùbojo pé fìtínà lè wáyé, ni ìjọ̀ba ba ṣòfin, láti dín jàgídí-jàgan àjọ̀dún yìí kù, ni wọn bá ṣàgbékalẹ̀ onírúurú òfin láàrin ọdún 1950 láti gbẹ́sẹ̀ lé àjọ̀dún yìí. Ní ọdún 1951, àwọn ọmọ-onílẹ̀ ti wọn rúfin yìí ni wọn jù sí àtìmọ́lé títí dì ìgbà tí gbogbo ìlú pariwo lé ìjọba lórí láti dá wọn sílẹ̀. Ìtàpá sí òfin gbígbẹ́sẹ̀ lé àjọ̀dún tomati tí ó gbajúgbajà jùlọ wáyé ní ọdún 1957 nígbà tí àwọn tí wọn faramọ́ àjọ̀dún yìí ṣe ìsìnkú aláwádà kan fún tomati pẹ̀lú pósí àti ìwọ́de. Lẹ́yìn ọdún 1957, ni ìjọba ìbílẹ̀ bá gbà lati pẹ̀lú ọbọ jẹko wọn, wọn gbé àwọṅ ìlànà kan kalẹ̀, wọn sì fọwọ́sí ìṣẹ̀dálẹ̀ jákujàku náà. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé tomato ni ó ni àjọ̀dún yìí, àṣeyẹ ọlọ́ṣẹ̀ kan yóò ṣaájú àṣekágbá àjọ̀dún náà. Bí í ṣíṣe àyájọ àwọn ẹni mímọ́ ìlú Buñol, ti Maria Wundia àti ti Ẹni-Mímọ́ Louis Bertrand, pẹ̀lú àwọn ìwọ́de ojú-pópó, torin-tìlù, àti yínyin bísìkò ní bí àwọn ara ilẹ́ Spain ti máa n ṣe. Láti gba agbára silẹ de gídígbò tí n bọ̀ lọ́nà, wọn yóò bu oúnjẹ paella bà-n-tà-bàn-tà fun olúkúlukú ní àìsùn ọjọ́ ìjàdù náà, èyí tí í ṣẹ àwọn ounjẹ àdáyébá bí ìrẹsì, ẹran-òun-ẹja-odò, ìyẹ̀fun safuroni àti òróró ólífì. Lọ́jọ òní, àjọ̀dún kò-lókùn-lọ́rùn yìí ti ni ìjánu díẹ̀díẹ̀ báyíì. Àwọn aláàtò-àjọ̀dún ti ṣe é débi pé kí wọn lọ wá onírúurú àwọn ẹ̀sà tomati ní tìtorí àyẹyẹ ọlọ́dọọdún náà. Àjọ̀dún máa n bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́wàá àárọ̀ nígbàtí àwọn olùkópa yóò sáré láti re ekìrí ẹran kan tí a so mọ́ orí òpó kan tí n yọ̀ bọ̀lọ̀bọ̀lọ̀. Tí àwọn ònwòran yóò sì máa fọ́n omi lu àwọn olùdíje yìí bí wọn ti n kọrin tí wọn sì n jó kiri ojú-pópó. Nígbà tí aago sọ́ọ́sì bá lù méjìlá ọ̀sán, àwọn ọkọ̀-akẹ́rù tí wọn kún dẹ́nu yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ̀lú, tí ariwo “To-ma-ti. To-ma-ti yóò sí gba gbogbo afẹ́fẹ́ kíkankíkan. Lẹ́yìn náà, ni wọn máa rọ́ àgbá olómi, tí gudugbẹ̀-ètò yóò sì bẹ̀rẹ̀. Èyí ni àmí eré-yá fún títẹ̀ àti sísọ okò tomato ní gbogbo ọ̀nà yóòwù sí ẹni ti olúkúlùkù ba dojú kọ. Ọta tomato atamátàṣè ọlọ́nà-jíṅjìn, ọta pẹ̀kí-n-pẹ̀kí, àti ọta kòjìn-kò-súnmọ́. Ọ̀nàkọnà yòówù tí o ba yàn, nígbà tí àsìkò bá fi máa tó, bí ìwọ yóò ṣe máa wò (àti bí ara rẹ ṣe máa rí) máa yàtọ̀. Lẹ́yìn bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, wọn yóò fi àwọn sọ̀kò-sọ̀kò tí gbogbo ara wọn ti rin fún tomati sílẹ̀ kí wọn máa lúwẹ̀ẹ́ nínú pọtọpọ́tọ́ tí kòtilẹ̀ fi ibi kankan jọ tomato mọ́. Àgbá ẹlẹẹ̀kejì tí wọn bá rọ́ jásí pé àkókò gídígbò-gídìgbò ti parí ni yẹn. |